2 Samuel 20:23-26

Àwọn ìránṣẹ́ Dafidi

23 aJoabu sì ni olórí gbogbo ogun Israẹli;
Benaiah ọmọ Jehoiada sì jẹ́ olórí àwọn Kereti, àti ti àwọn Peleti.
24Adoniramu sì jẹ́ olórí àwọn agbowó òde;
Jehoṣafati ọmọ Ahiludi sì jẹ́ olùkọsílẹ̀ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní ìlú.
25Ṣefa sì jẹ́ akọ̀wé;
Sadoku àti Abiatari sì ni àwọn àlùfáà.
26Ira pẹ̀lú, ará Jairi ni ń ṣe àlùfáà lọ́dọ̀ Dafidi.
Copyright information for YorBMYO